Òtúá Òfún A

Òtúá Òfún A
Ifá payé eléyìun ó níí bàjé. Nnkann rè ó dùn.
Òtúá fun fùn fun
Awo Oyin ló díá fún Oyin
Ayé òún d‘n báyìí?
Wón ní kó rúbo
Wón láyée rè ó dùn
Òtúá fun fùn fun
Awo ado ló díá fún Àdò
Ayé òun dáa báyìí?
Wón ní kó rúbo
Wón láyée rè ó dáa
Òtúá fun fùn fun
Awo Ìfùùnfun Èlùjù ló díá fím Ìfùùnfun Èlùjù
Wón ní gobgboo wón ó sá káalè
Ebo ni wón ó se
Oyín rúbo tiè ó pé
Àdò rú tiè
Ó tèlé e
Ìfùùnfun náà rú tiè
Gbogboo won naa ni ón ní adùun tiwon
Ifá pé òun pé iré adùn
Ilée wón kún fún owó
Ó kún fún omo
N tó dún ní n se gégée won
Ayé ye wón
N nó wón wá n jó ní wón wá n yò
Ni wón n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Wón ní béè làwon Babaláwo tàwón wí
Òtúá fun fùn fun
Awo Oyin ló díá fún Oyin
Òtúá fun fùn fun
Awo Àdò ló díá fún Àdo
Òtúá fun fùn fun
Awo Ìfùùnfun Èlùjù lo díá fún Ìfùùnfùn Èlùjù
Níjóo wón n fomi ojú sògbérè iré
Wón ní wón ó rúbo
Oyin mò n hó o
Àdò n sù
Ìfùùnfun ò sì tun dákée tiè nígbà kan
Ayé dùn rinrin
Í dùn rinrin sì ni wón n wí.

Òtúá Òfún A
Ifá dice la vida de esta persona no se habría estropear. Su vida sería dulce.

Òtúá fun fùn fun
El Babaláwo de Oyin lanzo adivinación para Oyin
¿Mi vida sería buena? Él preguntó
Le pidieron que realizara sacrificio
Ellos le dijeron su vida sería dulce
Òtúá fun fùn fun
El Babaláwo de Àdò lanzo adivinación para Àdò
¿Mi vida sería buena? Él preguntó
Le pidieron que realizara sacrificio
Ellos le dijeron que su vida estaría bien
Òtúá fun fùn fun
El Babaláwo de Ìfùùnfun Èlùjù lanzó adivinación para Ìfùùnfun Èlùjù
Ellos también le pidieron que cuidara de la tierra
Y realizara sacrificio
Oyin realizó el sacrificio
Àdò también sacrificó lo propio
Siguiendo a Oyin
Ìfùùnfun también ofreció lo propio
Todos ellos tienen su dulzura respectiva y peculiar
Ifá le desea la dulzura de vida a esta persona
Sus casas se pusieron llenas de dinero
Se puso lleno de niños
El lado dulce de vida siempre se encontró con ellos
La vida los agradó a todos
Ellos empezaron a bailar y regocijar entonces
Ellos estaban alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Ellos dijeron que es como su Babaláwo dijo
Òtúá fun fùn fun
El Babaláwo de Oyin lanzo adivinación para Oyin
Òtúá fun fùn fun
El Babaláwo de Àdò lanzo adivinación para Àdò
Òtúá fun fùn fun
El Babaláwo de Ìfùùnfun Èlùjù lanzo adivinacion para Ìfùnfùnfun Èlùjù
En el día ellos estaban llorando debido a las cosas buenas
Les pidieron que realizaran el sacrificio
Oyin burbujea
Àdò espuma en su superficie
Ìfùùnfun tampoco dejó de hervir
La vida es ahora muy dulcemente
Es ahora muy dulce, es lo que ellos están percbiendo.

Òtúá Òfún B
Àkùsàba Àyàndà
Awo ilé Olúmèrí Àápáálá
A díá fún Olúmèrí Àápáálá
Omo ilé san wón ó joko lo
Níjó ti n sògbògbò àrùn
Ti n najú aláì le nde
Olúmèrí Àápáálá lárùn n se
Òún wáá le gbádùn gbogbo nnkan òun lójú ayé òun bayìí?
Wón ní ewúré kan ni kó rú
Ó rú ewúré kan
Wón se Ifá fún un
Wón dá a je ni
Àrùn ti n se Olúmérì ò san
Ó tún dìgbà kejì
Ó tún gbókè ìpòrí è kalè
Ó tún ní kí Olúmèrí ó rúbo
Epo ìgò méjì
Ewúré kan
Kée bòkè ìpòrì è
Ó tún fi bòkè ìpòrí è
Wón tún dá a je
Àrùn ti n se Olúmèrí ò san
Olúmèrí wáá to àwon Aláwo mìíìn lo
Àwon Àáyá dúdú igbó Òdó
Àwon wèrè pupa ònà ò padà
Àwon òtééré òtààrà
N ti n sàn télètélè kómi legbelegbe ó tóó dé E ye òun lóókan òbò wò!
Wón lÓlúmèrí, rúbo o
Wón léwúré kan lebo
Wón níre fún un
Olúmèrí Àápáálá lóun ò rú
Lákòókó
Àkúsàba Àyàndà ní kóun ó rú ewúré kan
Òún sì rú u
Ihun ti n se òun ò lo
Léèkejì
Wón tún ní kóun ó tún rú ewúré kan
Àti ìgò epo méjì
Kóun e bòkè ìpòrí òun
Òún fi bo òkè ìpòrí
Ihun ti n se òun ò san
Wón ní bóo ni wón ti n se é
Wón ní ngbà àwon bá sè é tán
Làwón n je é
Wón ní háà
Béè kóò
Wón ní àrùn ti n se ó tó kò ti ò lo un
Dandan ni kó san
Wón ní ìwo sá rùú ewúré ná
Wón wáá se obè ewúré sílè
Àwon Babaláwo ò tíì fowó kàn án
Wón ní kí wón o yánlè sí òkè ìpòrí Olúmèrí
Wón bá yánlè
Wón ní kí wón ó fún baálé
Wón méran fún baálé
Wón méran fún ìyáálè Ilé
Wón ní wón ó fún omoolé
Wón fún omo osú
Wón fún kèé bá woón pé
Wón ni gbogbo eni ti n be láròówótó
Wón ní wón ó móo gbé oúnje fún won
Wón bá bèrè síí fún won léran
Wón se béè tán
Eléyìín n pé yóó dáa
Tòhún n pé yóó dáa
Ihun ti n sOlúmèrí bá san
‘Ó ní àsé bIfá ò bá rÁwo’
‘Àsé kò níí jeun’?
‘Asé nnakan a móo dáa báyìí?
N ní wá n jó ní wá n yó
Ní n yin àwon Babaláwo
Àwon Babaláwo n yin Ifá
Ó ní béè làwon Babaláwo tòún wí
Àkúsàba Àyàndà
Awo Ilé Olímèrí Àápáálá
A díá fún Olúmèrí Àápáálá
Omo Ilé san wón ó joki lo
Níjó ti n sògbògbò àrùn
N según gbogbo
Tíkan ò lójú
Wón lébo ní ó se
Àkúsàba Àyàndà
Ó pewúré kìíní
Wón dá a je
N tí n se Olúmèrí ò san
Àkúsàba Àyàndà
Ó pewúré kejì
Wón dá a je
Àrùn ti n se Olúmèrí ò san
Ó wáá kàwon Àáyá dúdú igbó Òdó
Àwon Wèrè pupa ònà ò padà
Àwon Òtéérété òtààràtà n ti n sàn télètélè kómi legbelegbe ó tóo dé
Wón ní wón ó pa ewúré
Kí wón ó há ewúré fún gbogbo ará Ilé
Wón há farra oko
Èrò ti n be lónà
Òun náà je nbè
N ti n sOlúmèrí wáá san
Àkúsàba Àyàndà
Awo Ilé Olúmèrí Àápálá
BIfá ò rÀwo
Kò jeun

Òtúá Òfún B

Àkúsàba Àyàndà
El sacerdote de casa de Olúmèrí
Adivinación del lanzamiento para Olúmerí Àpáálá
El niño de Ilé san wón ó joko lo
En el día que él estaba alimentando una enfermedad
Y recorrió sin poder ponerse de pie
Es Olúmèrí Àápáálá que se afligió por una enfermedad
'Yo podría disfrutar todas mis cosas por mi tiempo de vida'? Él preguntó
Ellos le dijeron que ofreciera una cabra
Él ofreció la cabra
Ellos prepararon la cabra como sacrificio
Ellos lo comieron solo
La enfermedad de Olúmèrí se negó a sanar
La segunda ves
Ellos sacaron su Òkè Ìpòrí
Él le pidió a Olúmèrí que sacrificara de nuevo
Dos botellas de aceite de palma
Una cabra
Él debe usarlo para sacrificar a su Òkè Ìpòrí
Él hizo como aconsejaron
Ellos lo comieron solo
La enfermedad que aflige Olúmèrí no sanó
Olúmèrí consultó otro conjunto (puesto, juego) de sacerdotes entonces
Los sacerdotes 'Àáyá dúdú igbó Òdó
'Wèrè pupa ònà ò padà'
Òtéérété Òtààràtà
'N tí n sàn télètélè kómi legbelegbe ó tóó dé'
Por favor inwuire de Ifá que usa Ìbò para mí, él suplicó
'Olúmèrí Àápáálá; ofrezca sacrificio ' ellos también dijeron
'Usted sacrificaría una cabra'
'Ellos son fortunas buenas suficientes que esperan por usted' ellos concluyeron
'Yo no ofreceré sacrifique de nuevo' Olúmèrí dijo mas (algo, mas bien) grandemente
'En el primer caso'
'Àkúsaba Àyàndà me pidió que ofreciera una cabra'
'Yo lo hice'
'Mi enfermedad se negó a sanar'
'El segundo caso'
'Él me pidió que ofreciera otra cabra'
'Conmigo debe usarlo para sacrificar a mi Òkè ìpòrí
'Yo hice como dijeron'
La dolencia se negó a ir
'Cómo usted realizó el sacrificio'? ellos preguntaron
'Cuando nosotros terminamos la preparación', Olúmèrí continuó
'Nosotros lo comimos entonces'
'Ha'! los sacerdotes exclamaron
'Ésa no es la manera correcta de hacerlo'
'Pero ahora, que su enfermedad particular'
'Definitivamente sanaría'
'Usted debe intentar ofrecer una cabra simplemente', ellos lo animaron
Ellos cocinaron la cabra en un estofado
El Babaláwos no lo han tocado
Ellos pidieron cortar algunos trozos en la tierra delante del Ifá de Olúmèrí
Ellos cortaron algunos pedazos como dijeron
Ellos pidieron dar algunos al cabeza de la familia
Ellos dieron al cabeza de la familia
Ellos dieron un poco de carne a la mujer
Ellos dieron a omoolé
Ellos también compartieron el omo osú
Kèé bá wóóm pé no se omitió al compartir
Todas las gentes cerca de en su compuesto (mezcla, complejo)
Ellos pidieron dar la comida a todos ellos
Ellos dieron comida y carne a todos ellos
Después de hacer esto
El hombre cerca de oraría 'sería bueno'
El otro oraría 'estaría bien'
La enfermedad que aflige Olúmèrí entonces sana
'¿Para que si Ifá no ve a un sacerdote hábil' 'Él no comería?'
'¿Él no comería?'
¿Así que las cosas podrían ser buenas? Olúmèrí razonó alegremente
Él empezó a bailar y regocijar entonces
Él estaba alabando su Babaláwo
Su Babaláwo estaba alabando Ifá
Él dijo que es como su Babaláwo predijo
Àkúsàba Àyàndà
El sacerdote de la casa de Olúmèrí
Adivinación lanzada para Olúmèrí Àápáálá
El niño de Ilé san wón ó joko lo
En el día que él estaba alimentando una enfermedad
Y recorrió sin poder ponerse de pie
Él que prueba sus manos en todas las cosas
Sin hacer el avance
Le pidieron que realizara el sacrificio
Àkúsàba Àyàndà
Usted mató la primera cabra
Ellos lo comieron solo
La enfermedad de Olúmèrí no sanó
Àkúsàba Àyàndà
Ellos sacrificaron la segunda cabra
Usted lo comió solo
La enfermedad de Olúmèrí no sanó tampoco
Era entonces el giro de 'Àáyá dúdú Òdó'
'Nosotros somos pupa ònà ò padà'
'Òtéérété òtààràtà n tí n sàn télètélè kómi legbelegbe ó tóó dé'
Ellos pidieron que ellos mataran una cabra
Y comparta esos que viven en casa
Ellos deben compartir que viven en la granja
El transeúnte
Todos deben comer fuera de él
La enfermedad que aflige Olúmèrí entonces sanó
Àkúsàba Àyàndà
El sacerdote de Olúmèrí Àápálá
Si Ifá no ve un Babaláwo hábil
Él no comería.